Jeremiah 13:19
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ìlú tí ó wà ní gúúsù ni à ó tì pa, kò sì ní sí ẹnikẹ́ni láti ṣí wọn. Gbogbo Juda ni a ó kó lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn, gbogbo wọn ni a ó kó lọ ní ìgbèkùn pátápátá.
Jeremiah 13:19 in English
Jeremiah 13:19 · Berean Standard Bible
The cities of the Negev have been shut tight, and no one can open them. All Judah has been carried into exile, wholly taken captive.
Context
17Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fetísílẹ̀,
Èmi yóò sọkún ní ìkọ̀kọ̀
nítorí ìgbéraga yín.
Ojú mi yóò sun ẹkún kíkorò,
tí omi ẹkún, yóò sì máa sàn jáde,
nítorí a kó agbo Olúwa lọ ìgbèkùn. 18Sọ fún ọba àti ayaba pé,
“Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀,
ẹ sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ yín,
adé ògo yín bọ́ sí ilẹ̀ láti orí yín.” 19Àwọn ìlú tí ó wà ní gúúsù ni à ó tì pa,
kò sì ní sí ẹnikẹ́ni láti ṣí wọn.
Gbogbo Juda ni a ó kó lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn,
gbogbo wọn ni a ó kó lọ ní ìgbèkùn pátápátá. 20Gbé ojú rẹ sókè,
kí o sì wo àwọn tí ó ń bọ̀ láti àríwá.
Níbo ni agbo ẹran tí a fi sí abẹ́ àkóso rẹ wà;
àgùntàn tí ò ń mú yangàn. 21Kí ni ìwọ yóò wí nígbà tí Olúwa bá dúró lórí rẹ
àwọn tí o mú bí ọ̀rẹ́ àtàtà.
Ǹjẹ́ kò ní jẹ́ ìrora fún ọ
bí aboyún tó ń rọbí?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.