Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fetísílẹ̀, Èmi yóò sọkún ní ìkọ̀kọ̀ nítorí ìgbéraga yín. Ojú mi yóò sun ẹkún kíkorò, tí omi ẹkún, yóò sì máa sàn jáde, nítorí a kó agbo Olúwa lọ ìgbèkùn.

Jeremiah 13:17 in English

Jeremiah 13:17 · Berean Standard Bible

But if you do not listen, I will weep in secret because of your pride. My eyes will overflow with tears, because the LORD’s flock has been taken captive.

Context

15Gbọ́ kí o sì fetísílẹ̀, ẹ má ṣe gbéraga, nítorí Olúwa ti sọ̀rọ̀. 16Ẹ fi ògo fún Olúwa Ọlọ́run yín, kí ó tó mú òkùnkùn wá, àti kí ó tó mú ẹsẹ̀ yín tàsé lórí òkè tí ó ṣókùnkùn. Nígbà tí ẹ̀yin sì ń retí ìmọ́lẹ̀, òun yóò sọ ọ́ di òjìji yóò sì ṣe bi òkùnkùn biribiri. 17Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fetísílẹ̀, Èmi yóò sọkún ní ìkọ̀kọ̀ nítorí ìgbéraga yín. Ojú mi yóò sun ẹkún kíkorò, tí omi ẹkún, yóò sì máa sàn jáde, nítorí a kó agbo Olúwa lọ ìgbèkùn. 18Sọ fún ọba àti ayaba pé, “Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀, ẹ sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ yín, adé ògo yín bọ́ sí ilẹ̀ láti orí yín.” 19Àwọn ìlú tí ó wà ní gúúsù ni à ó tì pa, kò sì ní sí ẹnikẹ́ni láti ṣí wọn. Gbogbo Juda ni a ó kó lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn, gbogbo wọn ni a ó kó lọ ní ìgbèkùn pátápátá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.