Jeremiah 12:13
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àlìkámà ni wọn yóò gbìn, ṣùgbọ́n ẹ̀gún ni wọn yóò ká, wọn yóò fi ara wọn ṣe wàhálà, ṣùgbọ́n òfo ni èrè wọn. Kí ojú kí ó tì yín nítorí èrè yín, nítorí ìbínú gbígbóná Olúwa.
Jeremiah 12:13 in English
Jeremiah 12:13 · Berean Standard Bible
They have sown wheat but harvested thorns. They have exhausted themselves to no avail. Bear the shame of your harvest because of the fierce anger of the LORD.”
Context
11A ó sọ ọ́ di aṣálẹ̀ ilẹ̀
tí kò wúlò níwájú mi,
gbogbo ilẹ̀ ni yóò di ahoro
nítorí kò sí ẹnìkankan tí yóò náání. 12Gbogbo ibi gíga tí ó wà nínú aṣálẹ̀
ni àwọn apanirun ti gorí,
nítorí idà Olúwa yóò pa
láti ìkangun kìn-ín-ní dé ìkangun èkejì ilẹ̀ náà;
kò sí àlàáfíà fún gbogbo alààyè. 13Àlìkámà ni wọn yóò gbìn, ṣùgbọ́n ẹ̀gún ni wọn yóò ká,
wọn yóò fi ara wọn ṣe wàhálà, ṣùgbọ́n òfo ni èrè wọn.
Kí ojú kí ó tì yín nítorí èrè yín,
nítorí ìbínú gbígbóná Olúwa. 14Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Ní ti gbogbo àwọn aládùúgbò mi búburú tí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé ogún tí mo fún àwọn ènìyàn Israẹli mi, Èmi yóò fà wọ́n tu kúrò lórí ilẹ̀ wọn, èmi yóò fa ìdílé Juda tu kúrò ní àárín wọn. 15Ṣùgbọ́n tí mo bá fà wọ́n tu tán, Èmi yóò padà yọ́nú sí wọn. Èmi yóò sì padà fún oníkálùkù ní ogún ìní rẹ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ ìní oníkálùkù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.