Jeremiah 12:15
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n tí mo bá fà wọ́n tu tán, Èmi yóò padà yọ́nú sí wọn. Èmi yóò sì padà fún oníkálùkù ní ogún ìní rẹ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ ìní oníkálùkù.
Jeremiah 12:15 in English
Jeremiah 12:15 · Berean Standard Bible
But after I have uprooted them, I will once again have compassion on them and return each one to his inheritance and to his land.
Context
13Àlìkámà ni wọn yóò gbìn, ṣùgbọ́n ẹ̀gún ni wọn yóò ká,
wọn yóò fi ara wọn ṣe wàhálà, ṣùgbọ́n òfo ni èrè wọn.
Kí ojú kí ó tì yín nítorí èrè yín,
nítorí ìbínú gbígbóná Olúwa. 14Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Ní ti gbogbo àwọn aládùúgbò mi búburú tí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé ogún tí mo fún àwọn ènìyàn Israẹli mi, Èmi yóò fà wọ́n tu kúrò lórí ilẹ̀ wọn, èmi yóò fa ìdílé Juda tu kúrò ní àárín wọn. 15Ṣùgbọ́n tí mo bá fà wọ́n tu tán, Èmi yóò padà yọ́nú sí wọn. Èmi yóò sì padà fún oníkálùkù ní ogún ìní rẹ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ ìní oníkálùkù. 16Bí wọ́n bá sì kọ ìwà àwọn ènìyàn mi, tí wọ́n sì fi orúkọ mi búra wí pé, ‘Níwọ̀n bí Olúwa ń bẹ láààyè,’ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ́ àwọn ènìyàn mi láti fi Baali búra, nígbà náà ni a ó gbé wọn ró láàrín àwọn ènìyàn mi. 17Ṣùgbọ́n bí orílẹ̀-èdè kan kò bá gbọ́, Èmi yóò fà á tu pátápátá, èmi yóò sì pa wọ́n run,” ni Olúwa wí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.