Jeremiah 11:14
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Má ṣe gbàdúrà fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o bẹ̀bẹ̀ fún wọn, nítorí pé, Èmi kì yóò dẹtí sí wọn nígbà tí wọ́n bá ké pè mí ní ìgbà ìpọ́njú.
Jeremiah 11:14 in English
Jeremiah 11:14 · Berean Standard Bible
As for you, do not pray for these people. Do not raise up a cry or a prayer on their behalf, for I will not be listening when they call out to Me in their time of disaster.
Context
12Àwọn ìlú Juda àti àwọn ará Jerusalẹmu yóò lọ kégbe sí àwọn òrìṣà tí wọ́n ń sun tùràrí sí; àwọn òrìṣà náà kò ní ràn wọ́n lọ́wọ́ ní ìgbà tí ìpọ́njú náà bá dé. 13Ìwọ Juda, bí iye àwọn ìlú rẹ, bẹ́ẹ̀ iye àwọn òrìṣà rẹ; bẹ́ẹ̀ ni iye pẹpẹ tí ẹ̀yin ti tẹ́ fún sísun tùràrí Baali ohun ìtìjú n nì ṣe pọ̀ bí iye òpópónà tí ó wà ní Jerusalẹmu.’ 14“Má ṣe gbàdúrà fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o bẹ̀bẹ̀ fún wọn, nítorí pé, Èmi kì yóò dẹtí sí wọn nígbà tí wọ́n bá ké pè mí ní ìgbà ìpọ́njú. 15“Kí ni olùfẹ́ mi ní í ṣe ní tẹmpili mi,
bí òun àti àwọn mìíràn ṣe ń hu oríṣìíríṣìí ìwà àrékérekè?
Ǹjẹ́ ẹran tí a yà sọ́tọ̀ lè mú ìjìyà kúrò lórí rẹ̀?
Nígbà tí ó bá ń ṣe iṣẹ́ búburú rẹ̀,
nígbà náà jẹ́ kí inú rẹ̀ kí ó dùn.” 16Olúwa pè ọ́ ní igi olifi
pẹ̀lú èso rẹ tí ó dára ní ojú.
Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ìjì líle
ọ̀wọ́-iná ni yóò sun ún
tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóò sì di gígé kúrò.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.