Jeremiah 11:16
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa pè ọ́ ní igi olifi pẹ̀lú èso rẹ tí ó dára ní ojú. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ìjì líle ọ̀wọ́-iná ni yóò sun ún tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóò sì di gígé kúrò.
Jeremiah 11:16 in English
Jeremiah 11:16 · Berean Standard Bible
The LORD once called you a flourishing olive tree, beautiful with well-formed fruit. But with a mighty roar He will set it on fire, and its branches will be consumed.
Context
14“Má ṣe gbàdúrà fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o bẹ̀bẹ̀ fún wọn, nítorí pé, Èmi kì yóò dẹtí sí wọn nígbà tí wọ́n bá ké pè mí ní ìgbà ìpọ́njú. 15“Kí ni olùfẹ́ mi ní í ṣe ní tẹmpili mi,
bí òun àti àwọn mìíràn ṣe ń hu oríṣìíríṣìí ìwà àrékérekè?
Ǹjẹ́ ẹran tí a yà sọ́tọ̀ lè mú ìjìyà kúrò lórí rẹ̀?
Nígbà tí ó bá ń ṣe iṣẹ́ búburú rẹ̀,
nígbà náà jẹ́ kí inú rẹ̀ kí ó dùn.” 16Olúwa pè ọ́ ní igi olifi
pẹ̀lú èso rẹ tí ó dára ní ojú.
Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ìjì líle
ọ̀wọ́-iná ni yóò sun ún
tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóò sì di gígé kúrò. 17Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí ó dá ọ ti kéde ibi sí ọ, nítorí ilé Israẹli àti Juda ti ṣe ohun ibi, wọ́n sì ti mú inú bí mi, wọ́n ti ru ìbínú mi sókè nípa sísun tùràrí si Baali. 18Nítorí Olúwa fi ọ̀tẹ̀ wọn hàn mí mo mọ̀ ọ́n; nítorí ní àsìkò náà ó fi ohun tí wọ́n ń ṣe hàn mí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.