Jeremiah 11:17
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí ó dá ọ ti kéde ibi sí ọ, nítorí ilé Israẹli àti Juda ti ṣe ohun ibi, wọ́n sì ti mú inú bí mi, wọ́n ti ru ìbínú mi sókè nípa sísun tùràrí si Baali.
Jeremiah 11:17 in English
Jeremiah 11:17 · Berean Standard Bible
The LORD of Hosts, who planted you, has decreed disaster against you on account of the evil that the house of Israel and the house of Judah have brought upon themselves, provoking Me to anger by burning incense to Baal.”
Context
15“Kí ni olùfẹ́ mi ní í ṣe ní tẹmpili mi,
bí òun àti àwọn mìíràn ṣe ń hu oríṣìíríṣìí ìwà àrékérekè?
Ǹjẹ́ ẹran tí a yà sọ́tọ̀ lè mú ìjìyà kúrò lórí rẹ̀?
Nígbà tí ó bá ń ṣe iṣẹ́ búburú rẹ̀,
nígbà náà jẹ́ kí inú rẹ̀ kí ó dùn.” 16Olúwa pè ọ́ ní igi olifi
pẹ̀lú èso rẹ tí ó dára ní ojú.
Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ìjì líle
ọ̀wọ́-iná ni yóò sun ún
tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóò sì di gígé kúrò. 17Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí ó dá ọ ti kéde ibi sí ọ, nítorí ilé Israẹli àti Juda ti ṣe ohun ibi, wọ́n sì ti mú inú bí mi, wọ́n ti ru ìbínú mi sókè nípa sísun tùràrí si Baali. 18Nítorí Olúwa fi ọ̀tẹ̀ wọn hàn mí mo mọ̀ ọ́n; nítorí ní àsìkò náà ó fi ohun tí wọ́n ń ṣe hàn mí. 19Mo ti dàbí ọ̀dọ́-àgùntàn jẹ́ẹ́jẹ́ tí a mú lọ fún pípa; n kò mọ̀ pé wọ́n ti gbìmọ̀ búburú sí mi wí pé:
“Jẹ́ kí a run igi àti èso rẹ̀;
jẹ́ kí a gé e kúrò ní orí ilẹ̀ alààyè,
kí a má lè rántí orúkọ rẹ̀ mọ́.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.