Jeremiah 11:13
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ Juda, bí iye àwọn ìlú rẹ, bẹ́ẹ̀ iye àwọn òrìṣà rẹ; bẹ́ẹ̀ ni iye pẹpẹ tí ẹ̀yin ti tẹ́ fún sísun tùràrí Baali ohun ìtìjú n nì ṣe pọ̀ bí iye òpópónà tí ó wà ní Jerusalẹmu.’
Jeremiah 11:13 in English
Jeremiah 11:13 · Berean Standard Bible
Your gods are indeed as numerous as your cities, O Judah; the altars of shame you have set up—the altars to burn incense to Baal—are as many as the streets of Jerusalem.’
Context
11Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Èmi yóò mu ibi tí wọn kò ní le è yẹ̀ wá sórí wọn, bí wọ́n tilẹ̀ ké pè mí èmi kì yóò fetí sí igbe wọn. 12Àwọn ìlú Juda àti àwọn ará Jerusalẹmu yóò lọ kégbe sí àwọn òrìṣà tí wọ́n ń sun tùràrí sí; àwọn òrìṣà náà kò ní ràn wọ́n lọ́wọ́ ní ìgbà tí ìpọ́njú náà bá dé. 13Ìwọ Juda, bí iye àwọn ìlú rẹ, bẹ́ẹ̀ iye àwọn òrìṣà rẹ; bẹ́ẹ̀ ni iye pẹpẹ tí ẹ̀yin ti tẹ́ fún sísun tùràrí Baali ohun ìtìjú n nì ṣe pọ̀ bí iye òpópónà tí ó wà ní Jerusalẹmu.’ 14“Má ṣe gbàdúrà fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o bẹ̀bẹ̀ fún wọn, nítorí pé, Èmi kì yóò dẹtí sí wọn nígbà tí wọ́n bá ké pè mí ní ìgbà ìpọ́njú. 15“Kí ni olùfẹ́ mi ní í ṣe ní tẹmpili mi,
bí òun àti àwọn mìíràn ṣe ń hu oríṣìíríṣìí ìwà àrékérekè?
Ǹjẹ́ ẹran tí a yà sọ́tọ̀ lè mú ìjìyà kúrò lórí rẹ̀?
Nígbà tí ó bá ń ṣe iṣẹ́ búburú rẹ̀,
nígbà náà jẹ́ kí inú rẹ̀ kí ó dùn.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.