Jeremiah 10:8
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo wọn jẹ́ aláìlóye àti aṣiwèrè, wọ́n ń kọ́ ẹ̀kọ́ àwọn ère igi tí kò níláárí.
Jeremiah 10:8 in English
Jeremiah 10:8 · Berean Standard Bible
But they are altogether senseless and foolish, instructed by worthless idols made of wood!
Context
6Kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ Olúwa;
o tóbi orúkọ rẹ sì tóbi lágbára. 7Ta ni kò yẹ kí ó bẹ̀rù rẹ?
Ọba àwọn orílẹ̀-èdè?
Nítorí tìrẹ ni.
Láàrín àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní orílẹ̀-èdè
àti gbogbo ìjọba wọn,
kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ. 8Gbogbo wọn jẹ́ aláìlóye àti aṣiwèrè,
wọ́n ń kọ́ ẹ̀kọ́ àwọn ère igi tí kò níláárí. 9Fàdákà tí a ti kàn ni a mú wá láti Tarṣiṣi,
àti wúrà láti Upasi.
Èyí tí àwọn oníṣọ̀nà àti alágbẹ̀dẹ ṣe tí wọ́n
kùn ní àwọ̀ aró àti elése àlùkò,
èyí jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà. 10Ṣùgbọ́n Olúwa ni Ọlọ́run tòótọ́,
òun ni Ọlọ́run alààyè, ọba ayérayé.
Nígbà tí ó bá bínú, ayé yóò wárìrì;
orílẹ̀-èdè kò lè fi ara da ìbínú rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.