Jeremiah 10:9
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Fàdákà tí a ti kàn ni a mú wá láti Tarṣiṣi, àti wúrà láti Upasi. Èyí tí àwọn oníṣọ̀nà àti alágbẹ̀dẹ ṣe tí wọ́n kùn ní àwọ̀ aró àti elése àlùkò, èyí jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà.
Jeremiah 10:9 in English
Jeremiah 10:9 · Berean Standard Bible
Hammered silver is brought from Tarshish, and gold from Uphaz— the work of a craftsman from the hands of a goldsmith. Their clothes are blue and purple, all fashioned by skilled workers.
Context
7Ta ni kò yẹ kí ó bẹ̀rù rẹ?
Ọba àwọn orílẹ̀-èdè?
Nítorí tìrẹ ni.
Láàrín àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní orílẹ̀-èdè
àti gbogbo ìjọba wọn,
kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ. 8Gbogbo wọn jẹ́ aláìlóye àti aṣiwèrè,
wọ́n ń kọ́ ẹ̀kọ́ àwọn ère igi tí kò níláárí. 9Fàdákà tí a ti kàn ni a mú wá láti Tarṣiṣi,
àti wúrà láti Upasi.
Èyí tí àwọn oníṣọ̀nà àti alágbẹ̀dẹ ṣe tí wọ́n
kùn ní àwọ̀ aró àti elése àlùkò,
èyí jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà. 10Ṣùgbọ́n Olúwa ni Ọlọ́run tòótọ́,
òun ni Ọlọ́run alààyè, ọba ayérayé.
Nígbà tí ó bá bínú, ayé yóò wárìrì;
orílẹ̀-èdè kò lè fi ara da ìbínú rẹ̀. 11“Sọ èyí fún wọn: ‘Àwọn ọlọ́run kéékèèké tí kò dá ọ̀run àti ayé ni yóò ṣègbé láti ayé àti ní abẹ́ ọ̀run.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.