Onidajọ 21:11
Judges 21:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n ní, “Èyí ni ẹ̀yin yóò ṣe, ẹ pa gbogbo ọkùnrin àti gbogbo obìnrin tí kì í ṣe wúńdíá.”
Judges 21:11 in English
Judges 21:11 · Berean Standard Bible
This is what you are to do: Devote to destruction * every male, as well as every female who has had relations with a man.”
Context
9Nítorí pé nígbà tí wọ́n ka àwọn ènìyàn, wọ́n rí i pé kò sí ẹnìkankan láti inú àwọn ará Jabesi Gileadi tí ó wà níbẹ̀. 10Àwọn ìjọ ènìyàn náà sì rán ẹgbàá mẹ́fà (12,000) àwọn jagunjagun ọkùnrin, lọ sí Jabesi Gileadi wọ́n fún wọn ní àṣẹ pé, ẹ lọ fi idà kọlu gbogbo àwọn tí ó wà níbẹ̀, pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wẹ́wẹ́. 11Wọ́n ní, “Èyí ni ẹ̀yin yóò ṣe, ẹ pa gbogbo ọkùnrin àti gbogbo obìnrin tí kì í ṣe wúńdíá.” 12Wọ́n rí àwọn irinwó (400) ọ̀dọ́bìnrin tí kò mọ ọkùnrin rí nínú àwọn olùgbé Jabesi Gileadi, wọ́n sì mú wọn lọ sí ibùdó ní Ṣilo àwọn ará Kenaani. 13Gbogbo ìjọ àwọn ènìyàn sì ránṣẹ́ àlàáfíà sí àwọn Benjamini ní ihò àpáta Rimoni.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.