Onidajọ 21:13
Judges 21:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo ìjọ àwọn ènìyàn sì ránṣẹ́ àlàáfíà sí àwọn Benjamini ní ihò àpáta Rimoni.
Judges 21:13 in English
Judges 21:13 · Berean Standard Bible
Then the whole congregation sent a message of peace to the Benjamites who were at the rock of Rimmon.
Context
11Wọ́n ní, “Èyí ni ẹ̀yin yóò ṣe, ẹ pa gbogbo ọkùnrin àti gbogbo obìnrin tí kì í ṣe wúńdíá.” 12Wọ́n rí àwọn irinwó (400) ọ̀dọ́bìnrin tí kò mọ ọkùnrin rí nínú àwọn olùgbé Jabesi Gileadi, wọ́n sì mú wọn lọ sí ibùdó ní Ṣilo àwọn ará Kenaani. 13Gbogbo ìjọ àwọn ènìyàn sì ránṣẹ́ àlàáfíà sí àwọn Benjamini ní ihò àpáta Rimoni. 14Àwọn ẹ̀yà Benjamini náà sì padà ní àkókò náà, wọ́n sì fún wọn ní àwọn obìnrin Jabesi Gileadi. Ṣùgbọ́n wọn kò kárí gbogbo wọn. 15Àwọn ènìyàn náà sì káàánú nítorí ẹ̀yà Benjamini, nítorí Olúwa fi àlàfo kan sílẹ̀ nínú àwọn ẹ̀yà Israẹli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.