Native Bible

Judges 21:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ènìyàn náà sì káàánú nítorí ẹ̀yà Benjamini, nítorí Olúwa fi àlàfo kan sílẹ̀ nínú àwọn ẹ̀yà Israẹli.

Judges 21:15 in English

Judges 21:15 · Berean Standard Bible

The people grieved for Benjamin, because the LORD had made a void in the tribes of Israel.

Context

13Gbogbo ìjọ àwọn ènìyàn sì ránṣẹ́ àlàáfíà sí àwọn Benjamini ní ihò àpáta Rimoni. 14Àwọn ẹ̀yà Benjamini náà sì padà ní àkókò náà, wọ́n sì fún wọn ní àwọn obìnrin Jabesi Gileadi. Ṣùgbọ́n wọn kò kárí gbogbo wọn. 15Àwọn ènìyàn náà sì káàánú nítorí ẹ̀yà Benjamini, nítorí Olúwa fi àlàfo kan sílẹ̀ nínú àwọn ẹ̀yà Israẹli. 16Àwọn olórí ìjọ àwọn ènìyàn náà wí pé, “Kí ni àwa yóò ṣe láti rí aya fún àwọn ọkùnrin tí ó kù nígbà tí a ti pa gbogbo àwọn obìnrin Benjamini run?” 17Wọ́n sì wí pé, “Àwọn tí ó ṣẹ́kù tí wọ́n là nínú àwọn ẹ̀yà Benjamini ní láti ní ogún àti àrólé, kí ẹ̀yà kan nínú Israẹli má ṣe di píparun kúrò ní orí ilẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.