Onidajọ 21:17
Judges 21:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n sì wí pé, “Àwọn tí ó ṣẹ́kù tí wọ́n là nínú àwọn ẹ̀yà Benjamini ní láti ní ogún àti àrólé, kí ẹ̀yà kan nínú Israẹli má ṣe di píparun kúrò ní orí ilẹ̀.
Judges 21:17 in English
Judges 21:17 · Berean Standard Bible
They added, “There must be heirs for the survivors of Benjamin, so that a tribe of Israel will not be wiped out.
Context
15Àwọn ènìyàn náà sì káàánú nítorí ẹ̀yà Benjamini, nítorí Olúwa fi àlàfo kan sílẹ̀ nínú àwọn ẹ̀yà Israẹli. 16Àwọn olórí ìjọ àwọn ènìyàn náà wí pé, “Kí ni àwa yóò ṣe láti rí aya fún àwọn ọkùnrin tí ó kù nígbà tí a ti pa gbogbo àwọn obìnrin Benjamini run?” 17Wọ́n sì wí pé, “Àwọn tí ó ṣẹ́kù tí wọ́n là nínú àwọn ẹ̀yà Benjamini ní láti ní ogún àti àrólé, kí ẹ̀yà kan nínú Israẹli má ṣe di píparun kúrò ní orí ilẹ̀. 18Àwa kò le fi àwọn ọmọbìnrin wa fún wọn ní aya, nítorí tí àwa ọmọ Israẹli ti ṣe ìbúra yìí pé, ‘Ègún ni fún ẹnikẹ́ni tí ó fi aya fún ẹnikẹ́ni nínú ẹ̀yà Benjamini.’ ” 19Wọ́n sì wí pé, “Kíyèsi i ayẹyẹ ọlọ́dọọdún fún Olúwa wà ní Ṣilo ní ìhà àríwá Beteli àti ìhà ìlà-oòrùn òpópó náà tí ó gba Beteli kọjá sí Ṣekemu, àti sí ìhà gúúsù Lebona.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.