Onidajọ 21:16
Judges 21:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn olórí ìjọ àwọn ènìyàn náà wí pé, “Kí ni àwa yóò ṣe láti rí aya fún àwọn ọkùnrin tí ó kù nígbà tí a ti pa gbogbo àwọn obìnrin Benjamini run?”
Judges 21:16 in English
Judges 21:16 · Berean Standard Bible
Then the elders of the congregation said, “What should we do about wives for those who remain, since the women of Benjamin have been destroyed?”
Context
14Àwọn ẹ̀yà Benjamini náà sì padà ní àkókò náà, wọ́n sì fún wọn ní àwọn obìnrin Jabesi Gileadi. Ṣùgbọ́n wọn kò kárí gbogbo wọn. 15Àwọn ènìyàn náà sì káàánú nítorí ẹ̀yà Benjamini, nítorí Olúwa fi àlàfo kan sílẹ̀ nínú àwọn ẹ̀yà Israẹli. 16Àwọn olórí ìjọ àwọn ènìyàn náà wí pé, “Kí ni àwa yóò ṣe láti rí aya fún àwọn ọkùnrin tí ó kù nígbà tí a ti pa gbogbo àwọn obìnrin Benjamini run?” 17Wọ́n sì wí pé, “Àwọn tí ó ṣẹ́kù tí wọ́n là nínú àwọn ẹ̀yà Benjamini ní láti ní ogún àti àrólé, kí ẹ̀yà kan nínú Israẹli má ṣe di píparun kúrò ní orí ilẹ̀. 18Àwa kò le fi àwọn ọmọbìnrin wa fún wọn ní aya, nítorí tí àwa ọmọ Israẹli ti ṣe ìbúra yìí pé, ‘Ègún ni fún ẹnikẹ́ni tí ó fi aya fún ẹnikẹ́ni nínú ẹ̀yà Benjamini.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.