Native Bible

Judges 21:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ìjọ ènìyàn náà sì rán ẹgbàá mẹ́fà (12,000) àwọn jagunjagun ọkùnrin, lọ sí Jabesi Gileadi wọ́n fún wọn ní àṣẹ pé, ẹ lọ fi idà kọlu gbogbo àwọn tí ó wà níbẹ̀, pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wẹ́wẹ́.

Judges 21:10 in English

Judges 21:10 · Berean Standard Bible

So the congregation sent 12,000 of their most valiant men and commanded them: “Go and put to the sword those living in Jabesh-gilead, including women and children.

Context

8Wọ́n sì béèrè wí pé, “Èwo ni nínú ẹ̀yà Israẹli ni ó kọ̀ láti bá àwọn ènìyàn péjọ níwájú Olúwa ní Mispa?” Wọ́n rí i pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ó wa láti Jabesi Gileadi tí ó wá sí ibùdó fún àjọ náà. 9Nítorí pé nígbà tí wọ́n ka àwọn ènìyàn, wọ́n rí i pé kò sí ẹnìkankan láti inú àwọn ará Jabesi Gileadi tí ó wà níbẹ̀. 10Àwọn ìjọ ènìyàn náà sì rán ẹgbàá mẹ́fà (12,000) àwọn jagunjagun ọkùnrin, lọ sí Jabesi Gileadi wọ́n fún wọn ní àṣẹ pé, ẹ lọ fi idà kọlu gbogbo àwọn tí ó wà níbẹ̀, pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wẹ́wẹ́. 11Wọ́n ní, “Èyí ni ẹ̀yin yóò ṣe, ẹ pa gbogbo ọkùnrin àti gbogbo obìnrin tí kì í ṣe wúńdíá.” 12Wọ́n rí àwọn irinwó (400) ọ̀dọ́bìnrin tí kò mọ ọkùnrin rí nínú àwọn olùgbé Jabesi Gileadi, wọ́n sì mú wọn lọ sí ibùdó ní Ṣilo àwọn ará Kenaani.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.