Onidajọ 21:8
Judges 21:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n sì béèrè wí pé, “Èwo ni nínú ẹ̀yà Israẹli ni ó kọ̀ láti bá àwọn ènìyàn péjọ níwájú Olúwa ní Mispa?” Wọ́n rí i pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ó wa láti Jabesi Gileadi tí ó wá sí ibùdó fún àjọ náà.
Judges 21:8 in English
Judges 21:8 · Berean Standard Bible
So they asked, “Which one of the tribes of Israel failed to come up before the LORD at Mizpah?” And, in fact, no one from Jabesh-gilead had come to the camp for the assembly.
Context
6Àwọn ọmọ Israẹli sì banújẹ́ fún àwọn arákùnrin wọn, àwọn ẹ̀yà Benjamini. Wọ́n wí pé, “A ti ké ẹ̀yà kan kúrò lára Israẹli lónìí.” 7Báwo ni a yóò ṣe rí aya fún àwọn tí ó ṣẹ́kù, nítorí àwa ti fi Olúwa búra láti má fi ọ̀kankan nínú àwọn ọmọbìnrin wa fún wọn ní aya. 8Wọ́n sì béèrè wí pé, “Èwo ni nínú ẹ̀yà Israẹli ni ó kọ̀ láti bá àwọn ènìyàn péjọ níwájú Olúwa ní Mispa?” Wọ́n rí i pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ó wa láti Jabesi Gileadi tí ó wá sí ibùdó fún àjọ náà. 9Nítorí pé nígbà tí wọ́n ka àwọn ènìyàn, wọ́n rí i pé kò sí ẹnìkankan láti inú àwọn ará Jabesi Gileadi tí ó wà níbẹ̀. 10Àwọn ìjọ ènìyàn náà sì rán ẹgbàá mẹ́fà (12,000) àwọn jagunjagun ọkùnrin, lọ sí Jabesi Gileadi wọ́n fún wọn ní àṣẹ pé, ẹ lọ fi idà kọlu gbogbo àwọn tí ó wà níbẹ̀, pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wẹ́wẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.