Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Má ṣe pe èyí ní ọ̀tẹ̀ gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn yìí pè ní ọ̀tẹ̀, má ṣe bẹ̀rù ohun tí wọ́n bá bẹ̀rù, má sì ṣe fòyà rẹ̀.

Isaiah 8:12 in English

Isaiah 8:12 · Berean Standard Bible

“Do not call conspiracy everything these people regard as conspiracy. Do not fear what they fear;* do not live in dread.*

Context

10Ẹ gbìmọ̀ pọ̀, yóò sì di asán, ẹ gbèrò ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n kì yóò dúró, nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa. 11Olúwa bá mi sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀ o ìkìlọ̀ fún mi pé, èmi kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Ó wí pé, 12“Má ṣe pe èyí ní ọ̀tẹ̀ gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn yìí pè ní ọ̀tẹ̀, má ṣe bẹ̀rù ohun tí wọ́n bá bẹ̀rù, má sì ṣe fòyà rẹ̀. 13Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni Ẹni tí ìwọ yóò kà sí mímọ́, Òun ni kí o bẹ̀rù Òun ni kí àyà rẹ̀ fò ọ́, 14Òun yóò sì jẹ́ ibi mímọ́ ṣùgbọ́n fún ilé Israẹli méjèèjì ni yóò jẹ́, òkúta tí í mú ni kọsẹ̀ àti àpáta tí ó mú wọn ṣubú àti fún àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ni yóò jẹ́ tàkúté àti ìdẹ̀kùn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.