Isaiah 8:10
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ gbìmọ̀ pọ̀, yóò sì di asán, ẹ gbèrò ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n kì yóò dúró, nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa.
Isaiah 8:10 in English
Isaiah 8:10 · Berean Standard Bible
Devise a plan, but it will be thwarted; state a proposal, but it will not happen. For God is with us.*”
Context
8yóò sì gbá àárín Juda kọjá,
yóò sì ṣàn bò ó mọ́lẹ̀, yóò sì mú un dọ́rùn.
Nínà ìyẹ́ apá rẹ̀ yóò sì bo gbogbo ìbú ilẹ̀ rẹ̀,
ìwọ Emmanueli.” 9Ké ariwo ogun, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, kí a sì fọ́ ọ yín túútúú,
fetísílẹ̀, ẹ̀yin ilẹ̀ jíjìn réré.
Ẹ palẹ̀mọ́ fún ogun, kí a sì fọ́ ọ túútúú! 10Ẹ gbìmọ̀ pọ̀, yóò sì di asán,
ẹ gbèrò ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n kì yóò dúró,
nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa. 11Olúwa bá mi sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀ o ìkìlọ̀ fún mi pé, èmi kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Ó wí pé, 12“Má ṣe pe èyí ní ọ̀tẹ̀
gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn yìí pè ní ọ̀tẹ̀,
má ṣe bẹ̀rù ohun tí wọ́n bá bẹ̀rù,
má sì ṣe fòyà rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.