Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa bá mi sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀ o ìkìlọ̀ fún mi pé, èmi kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Ó wí pé,

Isaiah 8:11 in English

Isaiah 8:11 · Berean Standard Bible

For this is what the LORD has spoken to me with a strong hand, instructing me not to walk in the way of this people:

Context

9Ké ariwo ogun, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, kí a sì fọ́ ọ yín túútúú, fetísílẹ̀, ẹ̀yin ilẹ̀ jíjìn réré. Ẹ palẹ̀mọ́ fún ogun, kí a sì fọ́ ọ túútúú! 10Ẹ gbìmọ̀ pọ̀, yóò sì di asán, ẹ gbèrò ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n kì yóò dúró, nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa. 11Olúwa bá mi sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀ o ìkìlọ̀ fún mi pé, èmi kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Ó wí pé, 12“Má ṣe pe èyí ní ọ̀tẹ̀ gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn yìí pè ní ọ̀tẹ̀, má ṣe bẹ̀rù ohun tí wọ́n bá bẹ̀rù, má sì ṣe fòyà rẹ̀. 13Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni Ẹni tí ìwọ yóò kà sí mímọ́, Òun ni kí o bẹ̀rù Òun ni kí àyà rẹ̀ fò ọ́,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.