Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ǹjẹ́ èmi a ha máa mú wá sí ìrọbí kí èmi má sì mú ni bí?” ni Olúwa wí. “Ǹjẹ́ èmi a ha máa ṣé ilé ọmọ nígbà tí mo ń mú ìbí wá?” Ni Ọlọ́run yín wí.

Isaiah 66:9 in English

Isaiah 66:9 · Berean Standard Bible

Shall I bring a baby to the point of birth and not deliver it?” says the LORD. “Or will I who deliver close the womb?” says your God.

Context

7“Kí ó tó lọ sí ìrọbí, ó ti bímọ; kí ó tó di pé ìrora dé bá a, ó ti bí ọmọkùnrin. 8Ta ni ó ti gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí? Ta ni ó ti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí? Ǹjẹ́ a le bí orílẹ̀-èdè kan níjọ́ kan tàbí kí orílẹ̀-èdè lalẹ̀hù ní ìṣẹ́jú kan? Síbẹ̀síbẹ̀ Sioni bẹ̀rẹ̀ rírọbí bẹ́ẹ̀ ni ó sì bí àwọn ọmọ rẹ̀. 9Ǹjẹ́ èmi a ha máa mú wá sí ìrọbí kí èmi má sì mú ni bí?” ni Olúwa wí. “Ǹjẹ́ èmi a ha máa ṣé ilé ọmọ nígbà tí mo ń mú ìbí wá?” Ni Ọlọ́run yín wí. 10“Ẹ bá Jerusalẹmu yọ̀ kí inú yín kí ó sì dùn sí i, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀; ẹ yọ̀ gidigidi pẹ̀lú rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ó ti kẹ́dùn fún un. 11Nítorí pé ẹ̀yin yóò mu ẹ o sì ní ìtẹ́lọ́rùn nínú ọmú rẹ̀ tí ó tu ni lára, ẹ̀yin yóò mu àmuyó ẹ ó sì gbádùn nínú àkúnwọ́sílẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ rẹ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.