Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ta ni ó ti gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí? Ta ni ó ti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí? Ǹjẹ́ a le bí orílẹ̀-èdè kan níjọ́ kan tàbí kí orílẹ̀-èdè lalẹ̀hù ní ìṣẹ́jú kan? Síbẹ̀síbẹ̀ Sioni bẹ̀rẹ̀ rírọbí bẹ́ẹ̀ ni ó sì bí àwọn ọmọ rẹ̀.

Isaiah 66:8 in English

Isaiah 66:8 · Berean Standard Bible

Who has heard of such as this? Who has seen such things? Can a country be born in a day or a nation be delivered in an instant? Yet as soon as Zion was in labor, she gave birth to her children.

Context

6Gbọ́ rògbòdìyàn láti ìlú wá, gbọ́ ariwo náà láti tẹmpili wá! Ariwo tí Olúwa ní í ṣe tí ó ń san án fún àwọn ọ̀tá rẹ̀ ohun tí ó tọ́ sí wọn. 7“Kí ó tó lọ sí ìrọbí, ó ti bímọ; kí ó tó di pé ìrora dé bá a, ó ti bí ọmọkùnrin. 8Ta ni ó ti gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí? Ta ni ó ti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí? Ǹjẹ́ a le bí orílẹ̀-èdè kan níjọ́ kan tàbí kí orílẹ̀-èdè lalẹ̀hù ní ìṣẹ́jú kan? Síbẹ̀síbẹ̀ Sioni bẹ̀rẹ̀ rírọbí bẹ́ẹ̀ ni ó sì bí àwọn ọmọ rẹ̀. 9Ǹjẹ́ èmi a ha máa mú wá sí ìrọbí kí èmi má sì mú ni bí?” ni Olúwa wí. “Ǹjẹ́ èmi a ha máa ṣé ilé ọmọ nígbà tí mo ń mú ìbí wá?” Ni Ọlọ́run yín wí. 10“Ẹ bá Jerusalẹmu yọ̀ kí inú yín kí ó sì dùn sí i, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀; ẹ yọ̀ gidigidi pẹ̀lú rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ó ti kẹ́dùn fún un.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.