Isaiah 66:7
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Kí ó tó lọ sí ìrọbí, ó ti bímọ; kí ó tó di pé ìrora dé bá a, ó ti bí ọmọkùnrin.
Isaiah 66:7 in English
Isaiah 66:7 · Berean Standard Bible
“Before she was in labor, she gave birth; before she was in pain, she delivered a boy.
Context
5Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa,
ẹ̀yin tí ẹ ń wárìrì nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀:
“Àwọn arákùnrin yín tí wọ́n kórìíra yín,
tí wọ́n ta yín nù nítorí orúkọ mi, wí pé,
‘Jẹ́ kí a yin Olúwa lógo,
kí a le rí ayọ̀ yín!’
Ṣùgbọ́n àwọn ni ojú yóò tì. 6Gbọ́ rògbòdìyàn láti ìlú wá,
gbọ́ ariwo náà láti tẹmpili wá!
Ariwo tí Olúwa ní í ṣe
tí ó ń san án fún àwọn ọ̀tá rẹ̀ ohun
tí ó tọ́ sí wọn. 7“Kí ó tó lọ sí ìrọbí,
ó ti bímọ;
kí ó tó di pé ìrora dé bá a,
ó ti bí ọmọkùnrin. 8Ta ni ó ti gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí?
Ta ni ó ti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí?
Ǹjẹ́ a le bí orílẹ̀-èdè kan níjọ́ kan
tàbí kí orílẹ̀-èdè lalẹ̀hù ní ìṣẹ́jú kan?
Síbẹ̀síbẹ̀ Sioni bẹ̀rẹ̀ rírọbí
bẹ́ẹ̀ ni ó sì bí àwọn ọmọ rẹ̀. 9Ǹjẹ́ èmi a ha máa mú wá sí ìrọbí
kí èmi má sì mú ni bí?”
ni Olúwa wí.
“Ǹjẹ́ èmi a ha máa ṣé ilé ọmọ
nígbà tí mo ń mú ìbí wá?”
Ni Ọlọ́run yín wí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.