Isaiah 66:11
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí pé ẹ̀yin yóò mu ẹ o sì ní ìtẹ́lọ́rùn nínú ọmú rẹ̀ tí ó tu ni lára, ẹ̀yin yóò mu àmuyó ẹ ó sì gbádùn nínú àkúnwọ́sílẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ rẹ̀.”
Isaiah 66:11 in English
Isaiah 66:11 · Berean Standard Bible
so that you may nurse and be satisfied at her comforting breasts; you may drink deeply and delight yourselves in her glorious abundance.
Context
9Ǹjẹ́ èmi a ha máa mú wá sí ìrọbí
kí èmi má sì mú ni bí?”
ni Olúwa wí.
“Ǹjẹ́ èmi a ha máa ṣé ilé ọmọ
nígbà tí mo ń mú ìbí wá?”
Ni Ọlọ́run yín wí. 10“Ẹ bá Jerusalẹmu yọ̀ kí inú yín kí ó sì dùn sí i,
gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀;
ẹ yọ̀ gidigidi pẹ̀lú rẹ̀,
gbogbo ẹ̀yin tí ó ti kẹ́dùn fún un. 11Nítorí pé ẹ̀yin yóò mu ẹ o sì ní ìtẹ́lọ́rùn
nínú ọmú rẹ̀ tí ó tu ni lára,
ẹ̀yin yóò mu àmuyó
ẹ ó sì gbádùn nínú àkúnwọ́sílẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ rẹ̀.” 12Nítorí báyìí ni Olúwa wí:
“Èmi yóò fún un ní àlàáfíà gẹ́gẹ́ bí odò
àti ọrọ̀ orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí ìṣàn omi;
ẹ̀yin yóò mu ọmú, a ó sì gbé yín ní apá rẹ̀
a ó bá yín ṣeré ní orúkún rẹ̀. 13Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti í tu ọmọ rẹ̀ nínú,
bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò tù yín nínú
a ó sì tù yín nínú lórí Jerusalẹmu.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.