Isaiah 65:21
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọn yó ò kọ́ ilé, wọn yóò sì gbé nínú wọn wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì jẹ èso wọn.
Isaiah 65:21 in English
Isaiah 65:21 · Berean Standard Bible
They will build houses and dwell in them; they will plant vineyards and eat their fruit.
Context
19Èmi yóò ṣe àjọyọ̀ lórí Jerusalẹmu
n ó sì ní inú dídùn nínú àwọn ènìyàn mi;
ariwo ẹkún àti igbe
ni a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀ mọ́. 20“Títí láé a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀
ọmọ ọwọ́ tí yóò gbé fún ọjọ́ díẹ̀,
tàbí àgbàlagbà tí kì yóò lo ọjọ́ ayé rẹ̀ tán;
ẹni tí ó bá kú ní ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún
ni a ó pè ní ọ̀dọ́mọdé;
ẹni tí kò ba le pé ọgọ́rùn-ún kan
ni a ó pè ní ẹni ìfibú. 21Wọn yó ò kọ́ ilé, wọn yóò sì gbé nínú wọn
wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì jẹ èso wọn. 22Wọn kì yóò kọ́ ilé fún ẹlòmíràn láti gbé,
tàbí kí wọn gbìn fún ẹlòmíràn láti jẹ.
Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí igi kan,
bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí;
àwọn àyànfẹ́ mi yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́
wọn fún ìgbà pípẹ́. 23Wọn kì yóò ṣe iṣẹ́ lásán,
wọn kí yóò bímọ fún wàhálà;
nítorí wọn yóò jẹ́ àwọn ènìyàn ti Olúwa bùkún fún,
àwọn àti àwọn ìrandíran wọn pẹ̀lú wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.