Isaiah 65:19
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò ṣe àjọyọ̀ lórí Jerusalẹmu n ó sì ní inú dídùn nínú àwọn ènìyàn mi; ariwo ẹkún àti igbe ni a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀ mọ́.
Isaiah 65:19 in English
Isaiah 65:19 · Berean Standard Bible
I will rejoice in Jerusalem and take delight in My people. The sounds of weeping and crying will no longer be heard in her.
Context
17“Kíyèsi i, Èmi yóò dá
àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun.
A kì yóò rántí ohun àtẹ̀yìnwá mọ́,
tàbí kí wọn wá sí ọkàn. 18Ṣùgbọ́n ẹ yọ̀ kí inú yín dùn títí láé
nínú ohun tí èmi yóò dá,
nítorí èmi yóò dá Jerusalẹmu láti jẹ́ ohun ìdùnnú
àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ohun ayọ̀. 19Èmi yóò ṣe àjọyọ̀ lórí Jerusalẹmu
n ó sì ní inú dídùn nínú àwọn ènìyàn mi;
ariwo ẹkún àti igbe
ni a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀ mọ́. 20“Títí láé a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀
ọmọ ọwọ́ tí yóò gbé fún ọjọ́ díẹ̀,
tàbí àgbàlagbà tí kì yóò lo ọjọ́ ayé rẹ̀ tán;
ẹni tí ó bá kú ní ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún
ni a ó pè ní ọ̀dọ́mọdé;
ẹni tí kò ba le pé ọgọ́rùn-ún kan
ni a ó pè ní ẹni ìfibú. 21Wọn yó ò kọ́ ilé, wọn yóò sì gbé nínú wọn
wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì jẹ èso wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.