Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Kíyèsi i, Èmi yóò dá àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun. A kì yóò rántí ohun àtẹ̀yìnwá mọ́, tàbí kí wọn wá sí ọkàn.

Isaiah 65:17 in English

Isaiah 65:17 · Berean Standard Bible

For behold, I will create new heavens and a new earth.* The former things will not be remembered, nor will they come to mind.

Context

15Ẹ̀yin yóò fi orúkọ yín sílẹ̀ fún àwọn àyànfẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí ègún; Olúwa Olódùmarè yóò sì pa yín, ṣùgbọ́n fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni òun yóò fún ní orúkọ mìíràn. 16Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàdúrà ìbùkún ní ilẹ̀ náà yóò ṣe é nípasẹ̀ Ọlọ́run òtítọ́; Ẹni tí ó bá búra ní ilẹ̀ náà yóò búra nípasẹ̀ Ọlọ́run òtítọ́. Nítorí ìyọnu àtijọ́ yóò di ìgbàgbé yóò sì fi ara sin kúrò lójú mi. 17“Kíyèsi i, Èmi yóò dá àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun. A kì yóò rántí ohun àtẹ̀yìnwá mọ́, tàbí kí wọn wá sí ọkàn. 18Ṣùgbọ́n ẹ yọ̀ kí inú yín dùn títí láé nínú ohun tí èmi yóò dá, nítorí èmi yóò dá Jerusalẹmu láti jẹ́ ohun ìdùnnú àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ohun ayọ̀. 19Èmi yóò ṣe àjọyọ̀ lórí Jerusalẹmu n ó sì ní inú dídùn nínú àwọn ènìyàn mi; ariwo ẹkún àti igbe ni a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀ mọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.