Isaiah 62:5
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́mọkùnrin tí í gbé ọ̀dọ́mọbìnrin níyàwó, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin rẹ yóò gbé ọ níyàwó Gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ṣe é yọ̀ lórí ìyàwó rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run rẹ yóò yọ̀ lórí rẹ.
Isaiah 62:5 in English
Isaiah 62:5 · Berean Standard Bible
For as a young man marries a young woman, so your sons will marry you; and as a bridegroom rejoices over his bride, so your God will rejoice over you.
Context
3Ìwọ yóò sì jẹ́ adé dídán ní ọwọ́ Olúwa,
adé ọba ní ọwọ́ Ọlọ́run rẹ. 4Wọn kì yóò pè ọ́ ní ìkọ̀sílẹ̀ mọ́
tàbí kí wọ́n pe ilẹ̀ rẹ ní ahoro.
Ṣùgbọ́n a ó máa pè ọ́ ní Hẹfsiba,
àti ilẹ̀ rẹ ní Beula;
nítorí Olúwa yóò yọ́nú sí ọ
àti ilẹ̀ rẹ ni a ó gbé níyàwó. 5Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́mọkùnrin tí í gbé ọ̀dọ́mọbìnrin níyàwó,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin rẹ yóò gbé ọ níyàwó
Gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ṣe é yọ̀ lórí ìyàwó rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run rẹ yóò yọ̀ lórí rẹ. 6Èmi ti fi olùṣọ́ ránṣẹ́ sórí odi rẹ ìwọ Jerusalẹmu;
wọn kì yóò lè dákẹ́ tọ̀sán tòru.
Ẹ̀yin tí ń ké pe Olúwa,
ẹ má ṣe fúnra yín ní ìsinmi, 7àti kí ẹ má ṣe fún òun pẹ̀lú ní ìsinmi
títí tí yóò fi fi ìdí Jerusalẹmu múlẹ̀
tí yóò sì fi ṣe ìyìn orí ilẹ̀ ayé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.