Isaiah 62:7
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
àti kí ẹ má ṣe fún òun pẹ̀lú ní ìsinmi títí tí yóò fi fi ìdí Jerusalẹmu múlẹ̀ tí yóò sì fi ṣe ìyìn orí ilẹ̀ ayé.
Isaiah 62:7 in English
Isaiah 62:7 · Berean Standard Bible
nor give Him any rest until He establishes Jerusalem and makes her the praise of the earth.
Context
5Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́mọkùnrin tí í gbé ọ̀dọ́mọbìnrin níyàwó,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin rẹ yóò gbé ọ níyàwó
Gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ṣe é yọ̀ lórí ìyàwó rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run rẹ yóò yọ̀ lórí rẹ. 6Èmi ti fi olùṣọ́ ránṣẹ́ sórí odi rẹ ìwọ Jerusalẹmu;
wọn kì yóò lè dákẹ́ tọ̀sán tòru.
Ẹ̀yin tí ń ké pe Olúwa,
ẹ má ṣe fúnra yín ní ìsinmi, 7àti kí ẹ má ṣe fún òun pẹ̀lú ní ìsinmi
títí tí yóò fi fi ìdí Jerusalẹmu múlẹ̀
tí yóò sì fi ṣe ìyìn orí ilẹ̀ ayé. 8Olúwa ti búra pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀
àti nípa agbára apá rẹ:
“Èmi kì yóò jẹ́ kí ìyẹ̀fun rẹ
di oúnjẹ fún ọ̀tá rẹ
bẹ́ẹ̀ ni àwọn àjèjì kì yóò mu wáìnì
tuntun rẹ mọ́
èyí tí ìwọ ti ṣe làálàá fún; 9ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá kóórè rẹ̀ ni yóò jẹ ẹ́,
tí wọn ó sì yin Olúwa,
àti àwọn tí wọ́n bá kó àjàrà jọ ni wọn ó mú un,
nínú àgbàlá ilé mímọ́ mi.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.