Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ta ni àwọn wọ̀nyí tí ń fò lọ bí i kurukuru, gẹ́gẹ́ bí àwọn àdàbà sí ìtẹ́ wọn?

Isaiah 60:8 in English

Isaiah 60:8 · Berean Standard Bible

Who are these who fly like clouds, like doves to their shelters?

Context

6Ọ̀wọ́ ìbákasẹ yóò bo gbogbo ilẹ̀ rẹ, àwọn ọ̀dọ́ ìbákasẹ Midiani àti Efani. Àti gbogbo wọn láti Ṣeba yóò wá, wọn yóò mú wúrà àti tùràrí lọ́wọ́ tí wọn yóò sì máa kéde ìyìn Olúwa. 7Gbogbo agbo ẹran ìlú Kedari ni a ó kójọ sọ́dọ̀ rẹ, àwọn àgbò ti Nebaioti yóò sìn ọ́; wọn yóò jẹ́ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi, bẹ́ẹ̀ ni n ó sì ṣe tẹmpili ògo mi lọ́ṣọ̀ọ́. 8“Ta ni àwọn wọ̀nyí tí ń fò lọ bí i kurukuru, gẹ́gẹ́ bí àwọn àdàbà sí ìtẹ́ wọn? 9Lóòtítọ́ àwọn erékùṣù bojú wò mí; ní ìṣíwájú ni àwọn ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi; mú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wá láti ọ̀nà jíjìn, pẹ̀lú fàdákà àti wúrà wọn, fún ti ọlá Olúwa Ọlọ́run rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli, nítorí òun ti fi ohun dídára ṣe ó lọ́ṣọ̀ọ́. 10“Àwọn àjèjì yóò tún ògiri rẹ mọ àwọn ọba wọn yóò sì sìn ọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ní ìbínú ni mo lù ọ́, ní àánú èmi yóò ṣe inú rere sí ọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.