Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lóòtítọ́ àwọn erékùṣù bojú wò mí; ní ìṣíwájú ni àwọn ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi; mú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wá láti ọ̀nà jíjìn, pẹ̀lú fàdákà àti wúrà wọn, fún ti ọlá Olúwa Ọlọ́run rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli, nítorí òun ti fi ohun dídára ṣe ó lọ́ṣọ̀ọ́.

Isaiah 60:9 in English

Isaiah 60:9 · Berean Standard Bible

Surely the islands * will wait for Me, with the ships of Tarshish * in the lead, to bring your children from afar, with their silver and gold, to the honor of the LORD your God, the Holy One of Israel, for He has glorified you.

Context

7Gbogbo agbo ẹran ìlú Kedari ni a ó kójọ sọ́dọ̀ rẹ, àwọn àgbò ti Nebaioti yóò sìn ọ́; wọn yóò jẹ́ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi, bẹ́ẹ̀ ni n ó sì ṣe tẹmpili ògo mi lọ́ṣọ̀ọ́. 8“Ta ni àwọn wọ̀nyí tí ń fò lọ bí i kurukuru, gẹ́gẹ́ bí àwọn àdàbà sí ìtẹ́ wọn? 9Lóòtítọ́ àwọn erékùṣù bojú wò mí; ní ìṣíwájú ni àwọn ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi; mú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wá láti ọ̀nà jíjìn, pẹ̀lú fàdákà àti wúrà wọn, fún ti ọlá Olúwa Ọlọ́run rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli, nítorí òun ti fi ohun dídára ṣe ó lọ́ṣọ̀ọ́. 10“Àwọn àjèjì yóò tún ògiri rẹ mọ àwọn ọba wọn yóò sì sìn ọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ní ìbínú ni mo lù ọ́, ní àánú èmi yóò ṣe inú rere sí ọ. 11Gbogbo ẹnu-bodè rẹ ni yóò wà ní ṣíṣí sílẹ̀, a kì yóò tì wọ́n ní ọ̀sán àti ní òru, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọkùnrin yóò le è kó ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè wá tí àwọn ọba wọn yóò ṣáájú ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ìṣẹ́gun.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.