Isaiah 60:12
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí pé orílẹ̀-èdè tàbí ilẹ̀ ọba tí kì yóò sìn ọ́ ni yóò parun; pátápátá ni yóò sì dahoro.
Isaiah 60:12 in English
Isaiah 60:12 · Berean Standard Bible
For the nation or kingdom that will not serve you will perish; it will be utterly destroyed.
Context
10“Àwọn àjèjì yóò tún ògiri rẹ mọ
àwọn ọba wọn yóò sì sìn ọ́.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ní ìbínú ni mo lù ọ́,
ní àánú èmi yóò ṣe inú rere sí ọ. 11Gbogbo ẹnu-bodè rẹ ni yóò wà ní ṣíṣí sílẹ̀,
a kì yóò tì wọ́n ní ọ̀sán àti ní òru,
tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọkùnrin yóò le è kó
ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè wá
tí àwọn ọba wọn yóò ṣáájú ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ìṣẹ́gun. 12Nítorí pé orílẹ̀-èdè tàbí ilẹ̀ ọba tí kì yóò sìn ọ́ ni yóò parun;
pátápátá ni yóò sì dahoro. 13“Ògo Lebanoni yóò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,
igi junifa, firi àti sípírẹ́ṣì papọ̀,
láti bu ọlá fún ilé ìsìn mi;
àti pé èmi yóò sì ṣe ibi ẹsẹ̀ mi lógo. 14Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àwọn apọ́nilójú rẹ yóò
wá foríbalẹ̀ fún ọ;
gbogbo àwọn tí ó ti kẹ́gàn rẹ ni wọn yóò tẹríba níwájú rẹ
wọn yóò sì pè ọ́ ní ìlú Olúwa,
Sioni ti Ẹni Mímọ́ Israẹli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.