Isaiah 60:13
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ògo Lebanoni yóò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, igi junifa, firi àti sípírẹ́ṣì papọ̀, láti bu ọlá fún ilé ìsìn mi; àti pé èmi yóò sì ṣe ibi ẹsẹ̀ mi lógo.
Isaiah 60:13 in English
Isaiah 60:13 · Berean Standard Bible
The glory of Lebanon will come to you— its cypress,* elm, and boxwood together— to adorn the place of My sanctuary, and I will glorify the place of My feet.
Context
11Gbogbo ẹnu-bodè rẹ ni yóò wà ní ṣíṣí sílẹ̀,
a kì yóò tì wọ́n ní ọ̀sán àti ní òru,
tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọkùnrin yóò le è kó
ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè wá
tí àwọn ọba wọn yóò ṣáájú ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ìṣẹ́gun. 12Nítorí pé orílẹ̀-èdè tàbí ilẹ̀ ọba tí kì yóò sìn ọ́ ni yóò parun;
pátápátá ni yóò sì dahoro. 13“Ògo Lebanoni yóò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,
igi junifa, firi àti sípírẹ́ṣì papọ̀,
láti bu ọlá fún ilé ìsìn mi;
àti pé èmi yóò sì ṣe ibi ẹsẹ̀ mi lógo. 14Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àwọn apọ́nilójú rẹ yóò
wá foríbalẹ̀ fún ọ;
gbogbo àwọn tí ó ti kẹ́gàn rẹ ni wọn yóò tẹríba níwájú rẹ
wọn yóò sì pè ọ́ ní ìlú Olúwa,
Sioni ti Ẹni Mímọ́ Israẹli. 15“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti kórìíra rẹ, a sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀,
láìsí ẹnìkan tí ó ń gba ọ̀dọ̀ rẹ kọjá,
Èmi yóò ṣe ọ́ ní ìṣògo ayérayé
àti ayọ̀ àtìrandíran.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.