Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti kórìíra rẹ, a sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀, láìsí ẹnìkan tí ó ń gba ọ̀dọ̀ rẹ kọjá, Èmi yóò ṣe ọ́ ní ìṣògo ayérayé àti ayọ̀ àtìrandíran.

Isaiah 60:15 in English

Isaiah 60:15 · Berean Standard Bible

Whereas you have been forsaken and despised, with no one passing through, I will make you an everlasting pride, a joy from age to age.

Context

13“Ògo Lebanoni yóò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, igi junifa, firi àti sípírẹ́ṣì papọ̀, láti bu ọlá fún ilé ìsìn mi; àti pé èmi yóò sì ṣe ibi ẹsẹ̀ mi lógo. 14Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àwọn apọ́nilójú rẹ yóò wá foríbalẹ̀ fún ọ; gbogbo àwọn tí ó ti kẹ́gàn rẹ ni wọn yóò tẹríba níwájú rẹ wọn yóò sì pè ọ́ ní ìlú Olúwa, Sioni ti Ẹni Mímọ́ Israẹli. 15“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti kórìíra rẹ, a sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀, láìsí ẹnìkan tí ó ń gba ọ̀dọ̀ rẹ kọjá, Èmi yóò ṣe ọ́ ní ìṣògo ayérayé àti ayọ̀ àtìrandíran. 16Ìwọ yóò mu wàrà gbogbo orílẹ̀-èdè a ó sì fun ọ́ ni ọmú àwọn ọba. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé, Èmi Olúwa, èmi ni Olùgbàlà rẹ, Olùdáǹdè rẹ, Alágbára ti Jakọbu. 17Dípò idẹ, èmi ó mú wúrà wá fún ọ, dípò fàdákà èmi ó mú irin wá. Dípò igi yóò mú idẹ wá fún ọ, àti irin dípò òkúta. Èmi yóò fi àlàáfíà ṣe àwọn ìjòyè rẹ àti òdodo gẹ́gẹ́ bí alákòóso rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.