Isaiah 59:8
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọ̀nà àlàáfíà èyí ni wọn kò mọ̀; kò sí òdodo ní ojú ọ̀nà wọn wọ́n ti sọ wọ́n dì ọ̀nà kọ́rọkọ̀rọ, kò sí ẹni tí ó tọ ọ̀nà yìí tí yóò rí àlàáfíà.
Isaiah 59:8 in English
Isaiah 59:8 · Berean Standard Bible
The way of peace they have not known,* and there is no justice in their tracks. They have turned them into crooked paths; no one who treads on them will know peace.
Context
6Òwú wọn kò wúlò fún aṣọ rírán;
wọn kò lè fi aṣọ tí wọ́n hun bo ara wọn.
Iṣẹ́ wọn jẹ́ ti ibi, ìwà jàǹdùkú sì kún ọwọ́ wọn. 7Ẹsẹ̀ wọn yára bọ́ sínú ẹ̀ṣẹ̀;
wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.
Èrò wọn sì jẹ́ èrò ibi;
ìparun àti ìdahoro ni ó wà ní ṣíṣe àmì ọ̀nà wọn. 8Ọ̀nà àlàáfíà èyí ni wọn kò mọ̀;
kò sí òdodo ní ojú ọ̀nà wọn
wọ́n ti sọ wọ́n dì ọ̀nà kọ́rọkọ̀rọ,
kò sí ẹni tí ó tọ ọ̀nà yìí tí yóò rí àlàáfíà. 9Nítorí èyí ni ẹ̀tọ́ fi jìnnà sí wa,
àti tí òdodo kò fi tẹ̀ wá lọ́wọ́.
A ń wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ jẹ́ òkùnkùn;
ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n à ń rìn nínú òjìji. 10Gẹ́gẹ́ bí afọ́jú à ń táràrà lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri
tí a ń wá ọ̀nà wa gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí kò ní ojú.
Ní ọ̀sán gangan ni à ń kọsẹ̀ bí ẹni pé alẹ́ ni;
láàrín alágbára àwa dàbí òkú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.