Isaiah 59:6
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Òwú wọn kò wúlò fún aṣọ rírán; wọn kò lè fi aṣọ tí wọ́n hun bo ara wọn. Iṣẹ́ wọn jẹ́ ti ibi, ìwà jàǹdùkú sì kún ọwọ́ wọn.
Isaiah 59:6 in English
Isaiah 59:6 · Berean Standard Bible
Their cobwebs cannot be made into clothing, and they cannot cover themselves with their works. Their deeds are sinful deeds, and acts of violence are in their hands.
Context
4Kò sí ẹni tí ó béèrè fún ìdájọ́ òdodo;
kò sí ẹni tí ó ro ẹjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú òtítọ́.
Wọ́n gbẹ́kẹ̀lé àwíjàre asán àti ọ̀rọ̀ irọ́;
wọ́n lóyún ìkà, wọn sì bí wàhálà. 5Wọn ń pa ẹ̀yin paramọ́lẹ̀
wọn sì ń ta owú aláǹtakùn.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹyin wọn yóò kú,
àti nígbà tí a pa ọ̀kan, paramọ́lẹ̀ ni ó jáde. 6Òwú wọn kò wúlò fún aṣọ rírán;
wọn kò lè fi aṣọ tí wọ́n hun bo ara wọn.
Iṣẹ́ wọn jẹ́ ti ibi, ìwà jàǹdùkú sì kún ọwọ́ wọn. 7Ẹsẹ̀ wọn yára bọ́ sínú ẹ̀ṣẹ̀;
wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.
Èrò wọn sì jẹ́ èrò ibi;
ìparun àti ìdahoro ni ó wà ní ṣíṣe àmì ọ̀nà wọn. 8Ọ̀nà àlàáfíà èyí ni wọn kò mọ̀;
kò sí òdodo ní ojú ọ̀nà wọn
wọ́n ti sọ wọ́n dì ọ̀nà kọ́rọkọ̀rọ,
kò sí ẹni tí ó tọ ọ̀nà yìí tí yóò rí àlàáfíà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.