Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kò sí ẹni tí ó béèrè fún ìdájọ́ òdodo; kò sí ẹni tí ó ro ẹjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú òtítọ́. Wọ́n gbẹ́kẹ̀lé àwíjàre asán àti ọ̀rọ̀ irọ́; wọ́n lóyún ìkà, wọn sì bí wàhálà.

Isaiah 59:4 in English

Isaiah 59:4 · Berean Standard Bible

No one calls for justice; no one pleads his case honestly. They rely on empty pleas; they tell lies; they conceive mischief and give birth to iniquity.

Context

2Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yín ló ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run yín; ẹ̀ṣẹ̀ yín ti fi ojú u rẹ̀ pamọ́ fún un yín tó bẹ́ẹ̀ tí òun kò fi le gbọ́. 3Nítorí ọwọ́ yín di aláìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀, àti ìka ọwọ́ yín fún ẹ̀bi. Ètè yín ń pa irọ́ púpọ̀, ahọ́n yín sì ń sọ̀rọ̀ nǹkan ibi. 4Kò sí ẹni tí ó béèrè fún ìdájọ́ òdodo; kò sí ẹni tí ó ro ẹjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú òtítọ́. Wọ́n gbẹ́kẹ̀lé àwíjàre asán àti ọ̀rọ̀ irọ́; wọ́n lóyún ìkà, wọn sì bí wàhálà. 5Wọn ń pa ẹ̀yin paramọ́lẹ̀ wọn sì ń ta owú aláǹtakùn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹyin wọn yóò kú, àti nígbà tí a pa ọ̀kan, paramọ́lẹ̀ ni ó jáde. 6Òwú wọn kò wúlò fún aṣọ rírán; wọn kò lè fi aṣọ tí wọ́n hun bo ara wọn. Iṣẹ́ wọn jẹ́ ti ibi, ìwà jàǹdùkú sì kún ọwọ́ wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.