Isaiah 59:2
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yín ló ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run yín; ẹ̀ṣẹ̀ yín ti fi ojú u rẹ̀ pamọ́ fún un yín tó bẹ́ẹ̀ tí òun kò fi le gbọ́.
Isaiah 59:2 in English
Isaiah 59:2 · Berean Standard Bible
But your iniquities have built barriers between you and your God, and your sins have hidden His face from you, so that He does not hear.
Context
1Lódodo ọwọ́ Olúwa kò kúrú láti gbàlà,
tàbí kí etí rẹ̀ wúwo láti gbọ́. 2Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yín ló ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run yín;
ẹ̀ṣẹ̀ yín ti fi ojú u rẹ̀ pamọ́ fún un yín
tó bẹ́ẹ̀ tí òun kò fi le gbọ́. 3Nítorí ọwọ́ yín di aláìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀,
àti ìka ọwọ́ yín fún ẹ̀bi.
Ètè yín ń pa irọ́ púpọ̀,
ahọ́n yín sì ń sọ̀rọ̀ nǹkan ibi. 4Kò sí ẹni tí ó béèrè fún ìdájọ́ òdodo;
kò sí ẹni tí ó ro ẹjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú òtítọ́.
Wọ́n gbẹ́kẹ̀lé àwíjàre asán àti ọ̀rọ̀ irọ́;
wọ́n lóyún ìkà, wọn sì bí wàhálà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.