Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gẹ́gẹ́ bí afọ́jú à ń táràrà lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri tí a ń wá ọ̀nà wa gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí kò ní ojú. Ní ọ̀sán gangan ni à ń kọsẹ̀ bí ẹni pé alẹ́ ni; láàrín alágbára àwa dàbí òkú.

Isaiah 59:10 in English

Isaiah 59:10 · Berean Standard Bible

Like the blind, we feel our way along the wall, groping like those without eyes. We stumble at midday as in the twilight; among the vigorous we are like the dead.

Context

8Ọ̀nà àlàáfíà èyí ni wọn kò mọ̀; kò sí òdodo ní ojú ọ̀nà wọn wọ́n ti sọ wọ́n dì ọ̀nà kọ́rọkọ̀rọ, kò sí ẹni tí ó tọ ọ̀nà yìí tí yóò rí àlàáfíà. 9Nítorí èyí ni ẹ̀tọ́ fi jìnnà sí wa, àti tí òdodo kò fi tẹ̀ wá lọ́wọ́. A ń wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ jẹ́ òkùnkùn; ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n à ń rìn nínú òjìji. 10Gẹ́gẹ́ bí afọ́jú à ń táràrà lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri tí a ń wá ọ̀nà wa gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí kò ní ojú. Ní ọ̀sán gangan ni à ń kọsẹ̀ bí ẹni pé alẹ́ ni; láàrín alágbára àwa dàbí òkú. 11Gbogbo wa là ń ké bí i beari; àwa pohùnréré ẹkún bí àdàbà. A ń wá ìdájọ́ òdodo ṣùgbọ́n kò sí; à ń wọ́nà fún ìtúsílẹ̀, ṣùgbọ́n ó jìnnà réré. 12Nítorí àwọn àṣìṣe wa pọ̀ níwájú rẹ, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sì ń jẹ́rìí takò wá. Àwọn àìṣedéédéé wa sì wà pẹ̀lú wa, àwa pẹ̀lú sì mọ àìṣedéédéé wa,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.