Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin ẹranko inú pápá, ẹ wá jẹ àwọn ẹranko inú igbó run!

Isaiah 56:9 in English

Isaiah 56:9 · Berean Standard Bible

Come, all you beasts of the field; eat greedily, all you beasts of the forest.

Context

7àwọn wọ̀nyí ni èmi yóò mú wá òkè mímọ́ mi, èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀ nínú ilé àdúrà mi. Ẹbọ sísun wọn àti ìrúbọ wọn, ni a ó tẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi; nítorí a ó máa pe ilé mi ní ilé àdúrà fún gbogbo orílẹ̀-èdè.” 8Olúwa Olódùmarè sọ wí pé— ẹni tí ó kó àwọn àtìpó Israẹli jọ: “Èmi yóò kó àwọn mìíràn jọ pẹ̀lú wọn yàtọ̀ sí àwọn tí a ti kójọ.” 9Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin ẹranko inú pápá, ẹ wá jẹ àwọn ẹranko inú igbó run! 10Àwọn olùṣọ́ Israẹli fọ́jú, gbogbo wọn ṣe aláìní ìmọ̀; gbogbo wọn jẹ́ adití ajá, wọn kò lè gbó; wọ́n sùn sílẹ̀ wọ́n ń lálàá, wọ́n fẹ́ràn láti máa sùn. 11Wọ́n jẹ́ àwọn ajá tí ó kúndùn púpọ̀; wọn kì í ní ànító. Wọ́n jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn tí kò ní òye; olúkúlùkù ń yà ṣọ́nà ara rẹ̀, ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn sì wá ère tirẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.