Isaiah 56:11
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n jẹ́ àwọn ajá tí ó kúndùn púpọ̀; wọn kì í ní ànító. Wọ́n jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn tí kò ní òye; olúkúlùkù ń yà ṣọ́nà ara rẹ̀, ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn sì wá ère tirẹ̀.
Isaiah 56:11 in English
Isaiah 56:11 · Berean Standard Bible
Like ravenous dogs, they are never satisfied. They are shepherds with no discernment; they all turn to their own way, each one seeking his own gain:
Context
9Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin ẹranko inú pápá,
ẹ wá jẹ àwọn ẹranko inú igbó run! 10Àwọn olùṣọ́ Israẹli fọ́jú,
gbogbo wọn ṣe aláìní ìmọ̀;
gbogbo wọn jẹ́ adití ajá,
wọn kò lè gbó;
wọ́n sùn sílẹ̀ wọ́n ń lálàá,
wọ́n fẹ́ràn láti máa sùn. 11Wọ́n jẹ́ àwọn ajá tí ó kúndùn púpọ̀;
wọn kì í ní ànító.
Wọ́n jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn tí kò ní òye;
olúkúlùkù ń yà ṣọ́nà ara rẹ̀,
ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn sì wá ère tirẹ̀. 12Igbe ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ni wí pé, “Wá, fún mi ní ọtí wáìnì!
Jẹ́ kí a mu ọtí líle wa lámu yó
ọ̀la yóò sì dàbí òní,
tàbí kí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.