Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

àwọn wọ̀nyí ni èmi yóò mú wá òkè mímọ́ mi, èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀ nínú ilé àdúrà mi. Ẹbọ sísun wọn àti ìrúbọ wọn, ni a ó tẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi; nítorí a ó máa pe ilé mi ní ilé àdúrà fún gbogbo orílẹ̀-èdè.”

Isaiah 56:7 in English

Isaiah 56:7 · Berean Standard Bible

I will bring them to My holy mountain and make them joyful in My house of prayer. Their burnt offerings and sacrifices will be accepted on My altar, for My house will be called a house of prayer * for all the nations.”

Context

5fún wọn ni Èmi yóò fún nínú tẹmpili àti àgbàlá rẹ̀ ìrántí kan àti orúkọ kan tí ó sàn ju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin, Èmi yóò fún wọn ní orúkọ ayérayé tí a kì yóò ké kúrò. 6Àti àwọn àjèjì tí ó so ara wọn mọ́ Olúwa láti sìn ín, láti fẹ́ orúkọ Olúwa àti láti foríbalẹ̀ fún un gbogbo àwọn tí ń pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́ àti tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin— 7àwọn wọ̀nyí ni èmi yóò mú wá òkè mímọ́ mi, èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀ nínú ilé àdúrà mi. Ẹbọ sísun wọn àti ìrúbọ wọn, ni a ó tẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi; nítorí a ó máa pe ilé mi ní ilé àdúrà fún gbogbo orílẹ̀-èdè.” 8Olúwa Olódùmarè sọ wí pé— ẹni tí ó kó àwọn àtìpó Israẹli jọ: “Èmi yóò kó àwọn mìíràn jọ pẹ̀lú wọn yàtọ̀ sí àwọn tí a ti kójọ.” 9Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin ẹranko inú pápá, ẹ wá jẹ àwọn ẹranko inú igbó run!

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.