Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa Olódùmarè sọ wí pé— ẹni tí ó kó àwọn àtìpó Israẹli jọ: “Èmi yóò kó àwọn mìíràn jọ pẹ̀lú wọn yàtọ̀ sí àwọn tí a ti kójọ.”

Isaiah 56:8 in English

Isaiah 56:8 · Berean Standard Bible

Thus declares the Lord GOD, who gathers the dispersed of Israel: “I will gather to them still others besides those already gathered.”

Context

6Àti àwọn àjèjì tí ó so ara wọn mọ́ Olúwa láti sìn ín, láti fẹ́ orúkọ Olúwa àti láti foríbalẹ̀ fún un gbogbo àwọn tí ń pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́ àti tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin— 7àwọn wọ̀nyí ni èmi yóò mú wá òkè mímọ́ mi, èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀ nínú ilé àdúrà mi. Ẹbọ sísun wọn àti ìrúbọ wọn, ni a ó tẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi; nítorí a ó máa pe ilé mi ní ilé àdúrà fún gbogbo orílẹ̀-èdè.” 8Olúwa Olódùmarè sọ wí pé— ẹni tí ó kó àwọn àtìpó Israẹli jọ: “Èmi yóò kó àwọn mìíràn jọ pẹ̀lú wọn yàtọ̀ sí àwọn tí a ti kójọ.” 9Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin ẹranko inú pápá, ẹ wá jẹ àwọn ẹranko inú igbó run! 10Àwọn olùṣọ́ Israẹli fọ́jú, gbogbo wọn ṣe aláìní ìmọ̀; gbogbo wọn jẹ́ adití ajá, wọn kò lè gbó; wọ́n sùn sílẹ̀ wọ́n ń lálàá, wọ́n fẹ́ràn láti máa sùn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.