Isaiah 54:15
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ bá ọ jà, kò ní jẹ́ láti ọwọ́ mi; ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ọ jà ni yóò túúbá fún ọ.
Isaiah 54:15 in English
Isaiah 54:15 · Berean Standard Bible
If anyone attacks you, it is not from Me; whoever assails you will fall before you.
Context
13Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ ni Olúwa yóò kọ́,
àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò jẹ́ ńlá àti púpọ̀. 14Ní òdodo ni a ó fi ìdí rẹ kalẹ̀
ìwà ipá yóò jìnnà sí ọ
o kò ní bẹ̀rù ohunkóhun,
ìpayà la ó mú kúrò pátápátá;
kò ní súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ. 15Bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ bá ọ jà, kò ní jẹ́ láti ọwọ́ mi;
ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ọ jà ni yóò túúbá fún ọ. 16“Kíyèsi i, èmi ni ó dá alágbẹ̀dẹ
tí ń fẹ́ iná èédú iná
tí ó sì ń mú ohun èlò wá tí ó bá iṣẹ́ rẹ mu.
Èmi náà sì ni ẹni tí ó dá apanirun láti ṣe iṣẹ́ ibi; 17kò sí ohun ìjà tí a ṣe sí ọ tí yóò lè ṣe nǹkan,
àti gbogbo ahọ́n tí ó dìde sí ọ ní ìdájọ́ ni ìwọ ó dá ní ẹ̀bi.
Èyí ni ogún àwọn ìránṣẹ́ Olúwa,
èyí sì ni ìdáláre wọn láti ọ̀dọ̀ mi,”
ni Olúwa wí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.