Isaiah 54:13
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ ni Olúwa yóò kọ́, àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò jẹ́ ńlá àti púpọ̀.
Isaiah 54:13 in English
Isaiah 54:13 · Berean Standard Bible
Then all your sons will be taught by the LORD,* and great will be their prosperity.
Context
11Ìwọ ìlú tí a pọ́n lójú, tí ìjì ń gbá kiri
tí a kò sì tù nínú,
Èmi yóò fi òkúta Tikuosi kọ́ ọ
àti ìpìlẹ̀ rẹ pẹ̀lú safire. 12Èmi yóò fi iyùn ṣe odi rẹ,
àwọn ẹnu-ọ̀nà ni a ó fi ohun èlò dáradára fún,
àti àwọn ògiri rẹ pẹ̀lú òkúta iyebíye. 13Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ ni Olúwa yóò kọ́,
àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò jẹ́ ńlá àti púpọ̀. 14Ní òdodo ni a ó fi ìdí rẹ kalẹ̀
ìwà ipá yóò jìnnà sí ọ
o kò ní bẹ̀rù ohunkóhun,
ìpayà la ó mú kúrò pátápátá;
kò ní súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ. 15Bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ bá ọ jà, kò ní jẹ́ láti ọwọ́ mi;
ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ọ jà ni yóò túúbá fún ọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.