Isaiah 54:12
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò fi iyùn ṣe odi rẹ, àwọn ẹnu-ọ̀nà ni a ó fi ohun èlò dáradára fún, àti àwọn ògiri rẹ pẹ̀lú òkúta iyebíye.
Isaiah 54:12 in English
Isaiah 54:12 · Berean Standard Bible
I will make your pinnacles of rubies, your gates of sparkling jewels, and all your walls of precious stones.
Context
10Bí a tilẹ̀ mi àwọn òkè ńlá
tí a sì ṣí àwọn òkè kékeré nídìí,
síbẹ̀síbẹ̀ ìfẹ́ àìkùnà mi fún ọ kì yóò yẹ̀ láéláé
tàbí májẹ̀mú àlàáfíà ni a ó mú kúrò,”
ni Olúwa, ẹni tí ó síjú àánú wò ọ́ wí. 11Ìwọ ìlú tí a pọ́n lójú, tí ìjì ń gbá kiri
tí a kò sì tù nínú,
Èmi yóò fi òkúta Tikuosi kọ́ ọ
àti ìpìlẹ̀ rẹ pẹ̀lú safire. 12Èmi yóò fi iyùn ṣe odi rẹ,
àwọn ẹnu-ọ̀nà ni a ó fi ohun èlò dáradára fún,
àti àwọn ògiri rẹ pẹ̀lú òkúta iyebíye. 13Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ ni Olúwa yóò kọ́,
àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò jẹ́ ńlá àti púpọ̀. 14Ní òdodo ni a ó fi ìdí rẹ kalẹ̀
ìwà ipá yóò jìnnà sí ọ
o kò ní bẹ̀rù ohunkóhun,
ìpayà la ó mú kúrò pátápátá;
kò ní súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.