Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

kò sí ohun ìjà tí a ṣe sí ọ tí yóò lè ṣe nǹkan, àti gbogbo ahọ́n tí ó dìde sí ọ ní ìdájọ́ ni ìwọ ó dá ní ẹ̀bi. Èyí ni ogún àwọn ìránṣẹ́ Olúwa, èyí sì ni ìdáláre wọn láti ọ̀dọ̀ mi,” ni Olúwa wí.

Isaiah 54:17 in English

Isaiah 54:17 · Berean Standard Bible

No weapon formed against you shall prosper, and you will refute every tongue that accuses you. This is the heritage of the servants of the LORD, and their vindication is from Me,” declares the LORD.

Context

15Bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ bá ọ jà, kò ní jẹ́ láti ọwọ́ mi; ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ọ jà ni yóò túúbá fún ọ. 16“Kíyèsi i, èmi ni ó dá alágbẹ̀dẹ tí ń fẹ́ iná èédú iná tí ó sì ń mú ohun èlò wá tí ó bá iṣẹ́ rẹ mu. Èmi náà sì ni ẹni tí ó dá apanirun láti ṣe iṣẹ́ ibi; 17kò sí ohun ìjà tí a ṣe sí ọ tí yóò lè ṣe nǹkan, àti gbogbo ahọ́n tí ó dìde sí ọ ní ìdájọ́ ni ìwọ ó dá ní ẹ̀bi. Èyí ni ogún àwọn ìránṣẹ́ Olúwa, èyí sì ni ìdáláre wọn láti ọ̀dọ̀ mi,” ni Olúwa wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.