Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

ẹ wo Abrahamu baba yín, àti Sara, ẹni tó bí i yín. Nígbà tí mo pè é, òun nìkan ni, Èmi sì bùkún un, mo sì ṣọ́ ọ di ọ̀pọ̀lọpọ̀.

Isaiah 51:2 in English

Isaiah 51:2 · Berean Standard Bible

Look to Abraham your father, and to Sarah who gave you birth. When I called him, he was but one; then I blessed him and multiplied him.

Context

1“Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin tí ó ń lépa òdodo àti ẹ̀yin tí ń wá Olúwa. Wo àpáta, nínú èyí tí a ti gé yín jáde àti ihò òkúta níbi tí a ti gbẹ́ yín jáde; 2ẹ wo Abrahamu baba yín, àti Sara, ẹni tó bí i yín. Nígbà tí mo pè é, òun nìkan ni, Èmi sì bùkún un, mo sì ṣọ́ ọ di ọ̀pọ̀lọpọ̀. 3Dájúdájú, Olúwa yóò tu Sioni nínú yóò sì bojú àánú wo gbogbo ahoro rẹ̀; Òun yóò sọ gbogbo aṣálẹ̀ rẹ̀ di Edeni, àti aṣálẹ̀ rẹ̀ yóò rí bí ọgbà Olúwa. Ayọ̀ àti inú dídùn ni a ó rí nínú rẹ̀, ọpẹ́ àti ariwo orín kíkọ. 4“Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin ènìyàn mi; gbọ́ tèmi, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè mi. Òfin yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde wá; ìdájọ́ mi yóò di ìmọ́lẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.