Isaiah 51:1
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin tí ó ń lépa òdodo àti ẹ̀yin tí ń wá Olúwa. Wo àpáta, nínú èyí tí a ti gé yín jáde àti ihò òkúta níbi tí a ti gbẹ́ yín jáde;
Isaiah 51:1 in English
Isaiah 51:1 · Berean Standard Bible
“Listen to Me, you who pursue righteousness, you who seek the LORD: Look to the rock from which you were cut, and to the quarry from which you were hewn.
Context
1“Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin tí ó ń lépa òdodo
àti ẹ̀yin tí ń wá Olúwa.
Wo àpáta, nínú èyí tí a ti gé yín jáde
àti ihò òkúta níbi tí a ti gbẹ́ yín jáde; 2ẹ wo Abrahamu baba yín,
àti Sara, ẹni tó bí i yín.
Nígbà tí mo pè é, òun nìkan ni,
Èmi sì bùkún un, mo sì ṣọ́ ọ di ọ̀pọ̀lọpọ̀. 3Dájúdájú, Olúwa yóò tu Sioni nínú
yóò sì bojú àánú wo gbogbo ahoro rẹ̀;
Òun yóò sọ gbogbo aṣálẹ̀ rẹ̀ di Edeni,
àti aṣálẹ̀ rẹ̀ yóò rí bí ọgbà Olúwa.
Ayọ̀ àti inú dídùn ni a ó rí nínú rẹ̀,
ọpẹ́ àti ariwo orín kíkọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.