Isaiah 51:4
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin ènìyàn mi; gbọ́ tèmi, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè mi. Òfin yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde wá; ìdájọ́ mi yóò di ìmọ́lẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè.
Isaiah 51:4 in English
Isaiah 51:4 · Berean Standard Bible
Pay attention to Me, My people, and listen to Me, My nation; for a law will go out from Me, and My justice will become a light to the nations; I will bring it about quickly.
Context
2ẹ wo Abrahamu baba yín,
àti Sara, ẹni tó bí i yín.
Nígbà tí mo pè é, òun nìkan ni,
Èmi sì bùkún un, mo sì ṣọ́ ọ di ọ̀pọ̀lọpọ̀. 3Dájúdájú, Olúwa yóò tu Sioni nínú
yóò sì bojú àánú wo gbogbo ahoro rẹ̀;
Òun yóò sọ gbogbo aṣálẹ̀ rẹ̀ di Edeni,
àti aṣálẹ̀ rẹ̀ yóò rí bí ọgbà Olúwa.
Ayọ̀ àti inú dídùn ni a ó rí nínú rẹ̀,
ọpẹ́ àti ariwo orín kíkọ. 4“Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin ènìyàn mi;
gbọ́ tèmi, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè mi.
Òfin yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde wá;
ìdájọ́ mi yóò di ìmọ́lẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè. 5Òdodo mi ń bọ̀ wá kíkankíkan,
ìgbàlà mi ń bọ̀ lójú ọ̀nà,
àti apá mi yóò sì mú ìdájọ́ wá
sí àwọn orílẹ̀-èdè.
Àwọn erékùṣù yóò wò mí
wọn yóò sì dúró ní ìrètí fún apá mi. 6Gbé ojú rẹ sókè sí àwọn ọ̀run,
wo ilẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀;
àwọn ọ̀run yóò pòórá bí èéfín,
ilẹ̀ yóò sì gbó bí ẹ̀wù
àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò kú gẹ́gẹ́ bí àwọn eṣinṣin.
Ṣùgbọ́n ìgbàlà mi yóò wà títí láé,
òdodo mi kì yóò yẹ̀ láé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.